Oriki Ogun

OGUN LAKAIYE
ỌSIN IMỌLẸ
OGUN ALADA MÉJÌ
OFI OKAN SANKO
OFI OKAN YENA
ỌJỌ OGUN NTI ORI OKE NBỌ
AṢỌ INA LỌ MU BORA
ẸWU ẸJẸ LOWO OGUN
ONILE OWO
ỌLỌ NA ỌLA
OGUN ONILE
KONGUN KONGUN
ỌRUN
OPỌN OMI SI ILE
FI ẸJẸ WẸ
OGUN AWỌN LE IJU
EGBE LEHIN ỌMỌ KAN
OGUN MÈJÈ LOGUN MI

Ogbeni Oja

Published by oloolutof

Urbanologist, Geographer, Traditionalist and Oral historian. ​I am a versatile, personable, computer literate and goal – driven achiever. I have good communication skill with ability to interact at different levels. I am self –motivated, can easily assimilate new ideals and quite adaptive to work in different environments. Studied in University of Jos, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife and University of Calabar.

22 thoughts on “Oriki Ogun

 1. nice but where is the rest…
  ogun meje logun mi
  ogun alara ni n gb’aja
  ogun onire a gb’agbo
  ogun elemosho a gb’esun isu
  ogun gbenagbena …. (can’t remember)
  xxxx
  ogun makinde ti d’ogun lehin odi
  bi o gba tapa a gba aboki… (signifying when ‘strangers’ were used as sacrifice

  Liked by 1 person

  1. ogun elemosho should read ‘ogun elemona’

   there’s this book we used to have at home during my childhood years (some 20,25 years ago), ‘Asa ibile Yoruba’ with a greenish cover. I didn’t think much of the book then but I’ll give anything now to have a copy. Such is life, my roots calls strongly even after after several years in foreign lands.

   Liked by 1 person

 2. Meje ni ire,
  Meje Loogun
  Ogun Alara ni je Aja
  Ogun oni gbajamo, irun ori ni je,
  Ogun gbenagbena amu eje
  Ogun Elemona, Oje igi ni mu
  Ogun onikola, aje igbin
  Ogun korakora ni je ekuru funfun,
  ogun onire, agba Agbo,
  Bi e ba gunyan nile, efi toogun sile,
  Bi e ba rooka nile, efi toogun sile,
  Nitori ogun lo roko,
  Ogun lo pa ajuba.

  Liked by 1 person

 3. This is both fantastic and wonderful, I never know some people still hold over culture in high esteem as this. My people, Ogun is one of the deities that our fore-fathers celebrated and they live much more longer than what we have now. Eyin omo Yoruba karo ojire, e maa je ka gba gbe isese nitoripe isese lagba o.

  Liked by 1 person

 4. This is the actual full “Oriki Ogun” as I learnt from Prof. Olojubu over 25years ago.
  Ogun lakaiye
  Ọsin mole
  Ogun alada méjì
  Ofi okan sanko
  Ofi okan yena
  Ọjo ogun nti ori oke bo
  Aso ina lo mu bora
  Ẹwu eje lowo
  Ogun onile owo
  Ọlo na ola
  Ogun onile Kongun kongun Ọrun
  Olomi ni ile feje we
  Olaso nile fimo kimo bora
  Ogun apon leyin iju
  Egbe lehin omo kan
  Ogun meje logun mi
  Ogun alara ni n gb’aja
  Ogun onire a gb’agbo
  Ogun ikole a gb’agbin
  Ogun ila a gb’esun isu
  Ogun akirin a gb’awo agbo
  Ogun elemono eran ahun ni je
  Ogun makinde ti dogun leyin odi
  Bi o ba gba tapa a gb’aboki
  A gba ukuuku a gba kemberi
  Nje nibo lati gbe pade ogun?
  A pade ogun nibi ija
  A pade re nibi ita
  A pade re nibi agbara eje ti nsan
  Agbara eje ti ndeni lorun
  Bi omi ago
  Bomode ba ndale
  Ki o mase da Ogun
  Oro Ogun leewo
  Ara Ogun kan go go go!

  Liked by 1 person

  1. Ogun lakaaye osin mole,onile kangunkangun ode orun, kolominile fejewe, kolaso nile ofi imokimo bora bi aso, ogun alada meji, onfi ikan lana, onfi ekeji sanko, olejeleje tiida omo eranko nitan, yankan bi ogbe ejo omo owere, koriko odo tiiru minimini, ogun kolaso meji mariwo laso ogun, aso alaso logun ngba bora. Ogun onile loma njaja, ogun onire amuje, ogun gbenagbena oje igi lonmu. Nijo ti ogun nti ikole orun bowa sile aye aso ina lofi bora, ewu eje logun wo. Ogun onile owo, olona ola, ogun aye nii ro irin, lonro oje lonro baba, ogun orun AJE lon ro. Orisa tobani ti Ogun kosi, yio fi enu rte hosu je. Won ni ki nbogun mi! Moti boo.

   Liked by 1 person

Leave a Reply

Please log in using one of these methods to post your comment:

WordPress.com Logo

You are commenting using your WordPress.com account. Log Out /  Change )

Twitter picture

You are commenting using your Twitter account. Log Out /  Change )

Facebook photo

You are commenting using your Facebook account. Log Out /  Change )

Connecting to %s

%d bloggers like this: